15 / 100

the Heart of the Matter Yoruba1

Download PDF Tracts

PATAKI OKAN NINU ORAN NA

Gegebi o seese ki o ti mo, wipe aisan okan ti npo si ju bi o ti wa tele lo. Bi eniyan ko ba ku nipase wipe awon kokoro arun kan ba a ja, a o si wa laaye titi di igba ti awon kan ninu eya ara wa ti o se koko yio bere si da ise sile. Okan ni eya ara akoko ti o saba ma nkoko da ise sile. Awon itoni pataki kan wa ti o le se iranwo lati mu ki okan re tun sise pe sii:

Ounje afaralokun se koko fun eyikeyi ninu eya ara wa. [“Emi (Jesu) ni onjẹ ìye nì ti o ti ọrun sọkalẹ wá: bi ẹnikẹni ba jẹ ninu onjẹ yi, yio yè titi lailai” Johannu 6:51]

Sisanra ju na je inira fun okan lati sise. [“Ṣugbọn ẹ mã kiyesara nyin, ki ọkàn nyin ki o máṣe kún fun wọ̀bia, ati fun ọti amupara, ati fun aniyan aiye yi” Luku 21:34]

A gbagbo wipe jije opolopo eran olora ma nfa ki opa ti o ngbe eje lati inu okan gan pa. [“Loni bi ẹnyin bá gbọ́ ohùn rẹ̀, ẹ máṣe sé ọkàn nyin le, bi igba imunibinu” Heberu 3:15]

Aibale aya le fa aisan okan. [“Ẹ máṣe aniyàn ohunkohun; ṣugbọn ninu ohun gbogbo, nipa adura ati ẹbẹ pẹlu idupẹ, ẹ mã fi ìbere nyin hàn fun Ọlọrun” Filippi 4:6]

Awon Ododo Oro ti o Ngunni L’okan

“Ọkàn enia kún fun ẹ̀tan jù ohun gbogbo lọ, o si buru jayi! tani o le mọ̀ ọ? 10 Emi, Oluwa, ni iwá awari ọkàn enia, emi ni ndan inu wò, ani lati fi fun olukuluku gẹgẹ bi ọ̀na rẹ̀, ati gẹgẹ bi eso iṣe rẹ̀” Jeremiah 17: 9-10

“Jù gbogbo ohun ipamọ́, pa aiya rẹ mọ́; nitoripe lati inu rẹ̀ wá ni orisun ìye” Owe 4:23

“…Nitori Oluwa a ma wá gbogbo aiya, o si mọ̀ gbogbo ete ironu…” 1Kronika 28:9

“Jesu si mọ̀ ìro inu wọn, o wipe, Nitori kili ẹnyin ṣe nrò buburu ninu nyin?” Mattiu 9:4

“Ọlọrun si ri pe ìwabuburu enia di pipọ̀ li aiye, ati pe gbogbo ìro ọkàn rẹ̀ kìki ibi ni lojojumọ.” Genesisi 6:5

“Irú ọkàn bayi iba ma wà ninu wọn, ki nwọn ki o le ma bẹ̀ru mi, ki nwọn ki o si le ma pa gbogbo ofin mi mọ́ nigbagbogbo, ki o le dara fun wọn, ati fun awọn ọmọ wọn titilai!” Deuteronomi 5:29

                                              Ona Abayo:

                                                Olorun le fun o ni okan titun

Emi o fi ọkàn titun fun nyin pẹlu, ẹmi titun li emi o fi sinu nyin, emi o si mu ọkàn okuta kuro lara nyin, emi o si fi ọkàn ẹran fun nyin” Esekieli 36:26

“Pe, bi iwọ ba fi ẹnu rẹ jẹwọ Jesu li Oluwa, ti iwọ si gbagbọ́ li ọkàn rẹ pe, Ọlọrun jí i dide kuro ninu okú, a o gbà ọ là. 10 Nitori ọkàn li a fi igbagbọ́ si ododo; ẹnu li a si fi ijẹwọ si igbala” Roomu 10:9-10

Ẹ jẹ ki a fi otitọ ọkàn sunmọ tosi ni ẹ̀kún igbagbọ́, ki a si wẹ̀ ọkàn wa mọ́ kuro ninu ẹri-ọkàn buburu, ki a si fi omi mimọ́ wẹ̀ ara wa nù” Heberu 10:22

                                                Mase je ki okan re daamu: Gbekele Olorun!

                                

You can find equivalent English tract @

The heart of the matter