10 / 100

Peace be unto you Yoruba 112

Download PDF Tracts

ALAFIA FUN O

Alafia – oro to dun ti o si tunilara! Alafia, ohun kan na ti okan eniyan npoungbe ti o si nlepa lojoojumo. Egbeegberun ni o nwa kiri, sugbon o dabi eni wipe nse ni o tun njina si won sii niwon egbeegberun ibuso. Alafia, owo ati oro ko lee ra a, ogbon ko lee sawari re, beeni okiki ati iyi ko le se okunfa re. Alafia, boya iwo na nwa a kiri laisi aseyori kan pato. Ni opo igba, nitori iwo se alaini alafia yi, nje o ko ti ma a kanra re mo elomiran, boya o tile ti gbero re ri lati pa ara re? O le e gbiyanju lati wa alafia nipase lilo oogun oloro; sugbon o je otito ti o daju wipe logan ti ogun oloro ba ti sise re tan, iru alafia bee yio di awati ni. Awon kan tile ma nlo sise asaro ninu idakeje ti awon ara India eyi ti won npe ni T.M. tabi Yoga. Iwadi kan nipa ise isegun ti won se laipe yi lori awon ti won ti nkopa ninu eto T.M. yi fun akoko ti o le ni odun kan ati aabo, fi han gbangba pe won ni idaamu okan ti o to isepo meji ti awon ti won kii kopa ninu T.M. tabi Yoga yi. Awon miran a tile fe sa fun idaamu okan nipa gbigbe igbe-aye idanikanwa, sugbon asehinwa asehinbo  won yio sese wa mo wipe inu won ni ohun ti o nfa idaamu okan wa kii se ninu awon elomiran ju bo ti ye lo. Sisa kuro laarin eniyan kan ran won lowo lati  fi ojukoju pelu idibaje ti o wa ninu iseda ti ara won gangan ni. Kin wa ni eredi iwalaaye bi a ko ba le ni alafia ati ifokanbale ninu idojuko awon idaamu wa ojoojumo?

Idi ti a fi mu iwe ilewo yi to o wa ni wipe a fe fi Eni na han o, Eni kan soso ti O le fun o ni ojulowo ifokanbale ati eyi ti o wa titi. O wipe, “Alafia ni mo fi fun yin. Alafia mi ni mo fi fun yin…E mase je ki okan yin daamu, beeni ki e ma si se foiya.” Eyi kii se oro asoje lasan, sugbon o je oro lati enu Eni na ti O fi Emi re lele lati fi han wipe Oun feran re, ati wipe Oun fe ki o dara fun o. Ko si eni na ti o le fun ni ni alafia, ayafi eni na ti o ni I ni ikawo. Eni kan wa ti O ni alafia ni ikawo ti o si se ileri lati fi i fun o. Oun na ni O nje Omo-Alade Alafia. Oruko re ni Jesu.

O le so wipe, “Emi ko gba pe enikan nje Jesu; bawo ni emi yio se ri ohun kan gba lowo eni ti emi ko ri ri?” Bi o ba se wipe o da eni ti o nje Jesu mo ni, iwo iba ti ni alafia yi. Idi ti ko fi tii je mimo fun o ni wipe, ohun kan wa ti o fi alafo si arin iwo ati Oun pelu Alafia ti o fe fi fun o, “ohun kan” na ni ese re. ni isale okan wa lohun gbogbo wa ni a mo ohun ti o dara ati eyi ti ko dara, nigbakugba ti a ba ti ko eti ikun si ohun eri okan inu wa ti o nso fun wa lati mase awon nkan kan, ohun ti a nse ni wipe a nko eti ikun si ohun Eni na ti O nfe lati fun wa ni alafia Re. Fi akoko die ronu nipa oro ayoka yi: “Iba se wipe eyin fiyesi ase mi, alafia yin iba dabi odo sisan, ati ododo yin “bi igbi omi okun.” “Bi awa ba jewo ese wa, olotito ati olododo ni oun lati dari ese wa ji wa ati lati we wa nu kuro ninu aisododo gbogbo.”

Owo re ni o ku si bayi. Bi o ba fe ni alafia nitooto, ohun ti o ni lati se ni lati yipada kuro ninu ohunkohun ti o mo wipe o je ohun ti ko dara ninu aye re, ki o si so fun Jesu ki o dariji o. O lagbara, O si setan lati dari ese yi o wu ki o le ti da ji o, nitori O fi emi Re lele fun o lori agbelebu ki o le ru ebi ese re ati ti emi. Lehin eyi se ipinnu lati gboran si Olorun lenu ninu ohun gbogbo ti O ba ti nfe lowo re. Bi o ba le se eyi, iwo yio ri alafia tooto, eyi ti o koja oye re, ti yio maa san jakejado aye re, Alafia yi ki yio si fi o sile lae.

Bi a ba ti mu ese re kuro, nigbana ni Jesu Omo-Alade Alafia yio di mimo fun o. Alafia, idande kuro lowo ese ati aisan, gbogbo re yio pade ara won laye re. Bi o ba ti gba A gegebi Oluwa ati Olugbala re, kii se idariji ese ati alafia nikan ni yio mu wa sinu okan re bikose iwosan fun ara re pelu. Oba Dafidi, eniti o ti ni iru iriri bi eyi ri, korin bayi, “Yin Oluwa iwo okan mi, ki iwo ki o mase gbagbe gbogbo oore re, eniti o dari ese re ji o ti o si wo gbogbo arun re san.” Je ki o da o loju wipe, nigbati o ba ti ba Jesu pade, Omo-Alade Alafia ti o si gba alafia Re, iberu, idaamu ati iponju yio poora kuro ninu okan re laisi inira. Bakanna nipa aye re, iwo na yio le mu iwon alafia ati ifokanbale die ba aye yi ti o ti ya perepere nipase ogun ati ikorira.

ADURA “Jesu Oluwa, Iwo ni Omo-Alade Alafia, mo si nilo alafia Re. Mo mo wipe ese mi ni o ya mi nipa pelu Re. Jowo dari ese mi ji mi ki o si we okan ese mi mo pelu eje Re iyebiye.

Loni, mo gba O gegebi Olorun mi ati Olugbala mi. Mo setan lati se ohunkohun ti o ba so fun mi, sugbon jowo ran mi lowo. Wo mi san Oluwa ki o si fin mi ni Alafia Re. Amin.”

 

You can find equivalent English tract @

Peace be unto you