17 / 100

real god_front12real god_back

Download PDF Tracts

OLORUN OTITO

Adun igbe aye yi se pataki si mi lopolopo. Emi, pelu aya ati omo mi ni ifojusona ojo iwaju ti o dara titi di igba ti dokita so fun mi wipe igba kukuru ni o ku fun mi lati lo ninu aye nitori jejere kan ti o dagba soke ninu gogongo mi. Ona kansoso ti ojo aye mi fi le sun siwaju die ni ki a se orisirisi awon ise abe kan fun mi eyi ti yio je ki a mu jejere yi kuro pelu gogongo mi. Isele yi mu ki aye mi duro gbagidi si oju kan.

Lehin opolopo awon ayewo, mo lo fun ise abe akoko. Wakati kan pere ni o ye ki o gba, sugbon o gba odidi ojo kan gbako. Irora iriri yi ko see mu mora. Bi mo se taji, mo kiyesi wipe won ti la ofun mi, won si ti ki opa oniho ti o nsise fun gogongo bo o. N ko le soro ayafi bi mo ba fi atanpako mi di enu opa oniho na.

Ni asale ojo kan ni nkan bii ojo mewa lehin ise abe na (eyi ti won so wipe o ni aseyori), eje bere si tu jade lati inu ofun ti o si kun enu mi bamu. Mo yara pe noosi. Laipe ni opo awon dokita ni won nsa soke sodo lati da bibi eje yi duro eyi ti o tesiwaju fun akoko ti o le ni wakati meta. “A ti sa gbogbo ipa wa” ni dokita kan so jade ninu ainireti re. Ni akiyesi wipe iku nkanlekun. Mo kigbe, “Jesu Oluwa, ran mi lowo\” Lesekanna eje na dawo duro – bi eje yi se dawo duro ni nkan se pelu oruko JESU-Kini idi? O dara, e je kin se alaye ohun ti o sele ki nto se ise abe akoko.

Eru nla ni o ko dabo mi lojiji bi mo ti nduro de  ojo ti a o se ise abe na, nigbana ni mo wa itunu lo si ile ijosin mi. Ni gbogbo ojo aye mi mo ti lero wipe Oloru wa ni ibi ti o jinna lopolopo, ati wipe Maria, iya Jesu  ni alarina laarin Olorun ati eniyan. Mo tun ni “eni mimo” kan ti mo ma ngbadura si ni akoko isoro. Nitorina ni Ojo Isinmi yi mo fi gbogbo agbara mi gbadura, sugbon si ibanuje okan fun mi, mo kuro ni ile ijosin bi mo ti lo sibe laisi iyato kan kan rara.

Bi mo ti npada sile, ainireti nla gba okan mi, o wa dabi eni wipe ko si ona lati gba ara mi sile kuro lowo eru nla yi. Ninu ero yi ni mo wa ti mo sadeede gbo ti orin ihinrere njade lati oju ferese ile kan, okan mi fa si ati wo ibe lo. Nigbati mo wole, mo ba ipejopo kekere bii eni mefa ti won nko orin. Nigbati ipade na pari, oluso aguntan na ki mi, o si wipe, Kini mo le se lati ran o lowo? Mo salaye bi ise abe ti o mbo lona yi se lagbara to lokan mi, mo si beere fun adura. O gbadura, ati lehinna si iyalenu mi, gbogbo awon eru yen poora lesekese!  O seleri lati be mi wo, o si tun fida mi loju wipe Jesu yio se iranwo.

O da mi loju gbangba, wipe adura awon eniyan wonyi ni o mu mi la ise abe akoko ja. Won ntesiwaju lati be mi wo ni gbogbo awon akoko yi won si ko mi lati mo sii nipa Jesu lati inu Bibeli. Oju mi wa la oye si ye mi fun igba akoko wipe Jesu nikan ni alarina laarin Olorun ati eniyan. Nigbayi ni mo wa gbadura ti mo si fi tayotayo gba A (Jesu) gegebi Oluwa ati Olugbala mi, mo wa ni iriri ayo ati idaniloju iwalaaye Re ti o sunmoni pekipeki.

Lehin igba ti ara mi ti da lehin ise abe akoko na, a fi mi sile lati ile iwosan lati ma lo sile, won si je ki o ye mi wipe mo gbodo ma wa si ile iwosan leekan lose.

Ni akotan, akoko to lati se ise abe ekeji ninu eyi ti won yio ti yo gogongo mu kuro gegebi ona abayo kansoso ti o ku lati mu emi mi gun si. Ni gbogbo awon akoko wonyi awon ore mi ti won je Kristiani wonyi ti fi Bibeli ye mi, Oro Olorun si fun mi ni iye titun. ‘…nitori emi li OLUWA ti o mu ọ lara dá’ (Eksodu 15:26), ati, ‘Olufẹ, emi ngbadura pe ninu ohun gbogbo ki o le mã dara fun ọ, ki o si mã wà ni ilera, ani bi o ti dara fun ọkàn rẹ’(3Johannu2) eyi ni awon ileri Olorun meji ti o nfun mi ni idaniloju pe Jesu ti wo mi san. Jesu funra Re so wipe, ‘Emi li ẹniti o mbẹ lãye, ti o si ti kú; si kiyesi i, emi si mbẹ lãye si i titi lai, Amin; mo si ní kọkọrọ ikú ati ti ipo-oku’ (Ifihan 1:18). Bi o tile je wipe gbogbo igba ni mo ti ma nni igbekele mi ninu dokita mi, ti mo si ma nsinmile gbogbo oro re; nisisiyi mo ti ri igbekekele ti o ga ju eyi lo ninu Jesu ati Oro Re.

Ni ale ojo kan lehin ti mo ti pada si ile iwosan fun ise abe keji, odomokurin ti o wa lori ibusun kan ti o sunmo itosi odo mi bere si kerora fun inira ninu ikun re. Ikedun nla gba okan mi, mo lo si ibi ibusun re, mo gbe owo mi soke mo si wipe, Jesu Oluwa, oju npon odomokunrin yi, o si ni irora nla. Jowo ran a lowo ki o si mu irora yi kuro: Lojukanna, o dide duro lori ese re a si wo o san patapata! Lehin iru iriri bi eyi, mo se ipinnu lojukanna wipe n ko ni se ise abe ekeji mo, nitoripe dajudaju Jesu kanna eniti o wo odomokunrin yi san le wo emi na san pelu. Ninu ose yi kanna ni mo kuro ni ile iwosan lo si ile, mo si ko eti ikun si ikilo dokita.

Ni ose ti o tele eyi, mo gba leta meta ti o nbeere idi ti n ko fi pada si ile iwosan. Leta keta tile to gbogbo awon otito ti o banileru nipa aisan ti o nse mi leseese ati gegebi alaye won, mo le ku. Siwaju si I, bi mo ba lo ku, ebi ko si lorun awon mo! Leta ti o kehin yi mu mi lo ro arojinle lori oro yi, sugbon bi mo ti nka Oro Olorun si i, beeni alafia ati igboya atinuwa nkun inu okan mi.

Lehin igba die, mo bere si ni inira lati mi nitori jejere ti o ti nwu di ibi ofun ti mo ngba mi. Gbogbo awon dokita ni o ti kilo fun mi wipe eyi yio sele, nisisiyi ni mo wa to mo wipe o di dandan ki a dan igbagbo mi ninu Jesu gegebi oluwosan wo.

Ni ojo kan bi mo ti ngbadura, ohun kan pe oruko mi o si wipe,’Bi o ba fe ko lo si inu ile ti o ti pe nile, kini iwo yio ko se?’ Nigbati mo ri wipe Oluwa ni, mo dahun wipe, ‘N o fo o nu ni:’ Lehinna ni o wa se alaye wipe, ‘Mo fe so o di Tempili mi; sugbon lakoko na, o gbodo di mimo patapata: Mo mo wipe Jesu ti dariji mi O si ti so mi di omo Rre Sugbon n ko I ti jewo awon ese mi patapata. Bi mo ti njewo awon ese na fun Oluwa, imolara aipe mi bo okan mi, ekun nikan ni mo kan le sun niwaju iwalaaye Re mimo. Jesu ku ni ipo mi lori agbelebu! Emi imoore nla fun ohun ti Jesu se kun inu okan mi, bi mo si ti ndide kuro ninu adura yi, Mo mo wipe mo ti di mimo, okan mi bale, mo si di ominira kuro ninu isoro lati mi.

Ni owuro ojo kan, inira lati mi, iru eyi ko tii sele si mi ri ni o ji mi loju oorun. Mimi mi kookan je ti ese kan aye ese kan orun. Bi mo ti nra pala lo sori eekun mi, mo kigbe lati isale okan mi wa wipe, ‘Jesu Oluwa, bi O ba wo mi san, ma se ohun kan fun O!’ O dabi eni wipe o ti nreti jijowo aye mi patapata fun ife Re. Lojiji mo wuko jale, ohun abami kan jade lati enu mi. Nigbati mo tu u si owo mi, mo wo ohun ti o je … jejere na ni o jade! Mo di ominira nikehin! Jesu ti wo mi san gegebi Oro Re ti seleri. Ogo ni fun Olorun! Sugbon o si tun ku iyanu kan ti mo gbodo so nipa Re.

Iru ayo nla wo ni o je lati le jeun ki nsi le maa mi bi eniyan yoku leekansi; sugbon o tun ku kini kan ninu ofun mi, eyi ni ageku opa ti won ki si mi lorun lati maa fi mi: Awon dokita koi ti yo o kuro, ni ero wipe ma tun pada wa fun ise abe eekeji. Nigba miran ohun kan yi maa kan mi ti yio si ma ni mi lara, nitorina mo bere si so fun Oluwa lati ba mi yo o kuro ni ofun mi bi o ti se fun jejere na. Ni akoko kookan ti mo ba ti ngbadura a sun wa soke ofun mi; nigbayi ni yio wa ma ro mi lopolopo ti yio si ma seje nigbamiran. Lehin o rehin  mo da adura gbigba duro lori eyi patapata ti mo si bere si yin Olorun fun ife Re.

Ni ojo kan ona miran lati ma gbadura so si mi lokan. Mo si so fun Jesu lati yo ohun ti o wa ni ofun mi yi dipo ki O gbe e jade. Bee gege ni ohun ti Oluwa fe se… O si se e! O yo o danu patapata!

Awon dokita so wipe n ko le lo ju osu mefa lo mo laye, sugbon mo ti lo opolopo odun lehin eyi mo situn wa laaye ati ni ilera, gbogbo eyi si ogo Re! Ko si amin apa kankan, ati wipe gbogbo ayewo ti mo ti  nse lati igba naa ni o nfi han wipe Jesu ti wo mi san patpata.

Lati igba na ni mo ti ngboran si Oluwa, gegebi Oro Re mo gba iribomi ti omi Jesu Oluwa si tun ti fi Emi Mimo baptisi mi, iriri meji ti o yato sira sugbon ti o se pataki fun omo Olorun kookan. (Ka Mattiu 28:19,ati Ise 2:38). Mo tesiwaju lati je olooto si ileri ti mo se fun Oluwa ni ojo ti o wo mi san. Mo n sin I mo si nso fun gbogbo eniyan awon ohun nla ti Jesu ti se ti O si tun le se.  Ohun ni Olorun otito!

Kin lo de ti iwo ko yonda aye re fun U loni? Bi o ba nsaisan tabi o ni isoro kankan, ke pe Jesu. Nitori O ti seleri wipe ‘Bi ẹnyin ba bère ohunkohun li orukọ mi, emi ó ṣe e.’(Johannu 14:14)

“Ohun ti Olorun le se ko se e fi pamo, ohun ti O ti se fun awon elomiran Oun yio se e fun o!“

Kelly M. Burke

 

You can find equivalent English tract @

The Real God