15 / 100

Jesus Loves, Jesus Helps Yoruba12

Download PDF Tracts

Jesu Ni Ife Jesu Nrannilowo

Ẹ wá sọdọ mi (Jesu) gbogbo ẹnyin ti nṣiṣẹ́, ti a si di ẹrù wuwo le lori, emi o si fi isimi fun nyin (Mattiu 11:28)

Ọlọrun fẹ araiye tobẹ̃ gẹ, ti o fi Ọmọ bíbi rẹ̀ kanṣoṣo (Jesu) funni, ki ẹnikẹni ti o ba gbà a gbọ́ má bà ṣegbé, ṣugbọn ki o le ni ìye ainipẹkun (Johannu 3:16)

Ọkunrin olupọnju yi kigbe pè, Oluwa (Jesu) si gbohùn rẹ̀, o si gbà a ninu gbogbo ipọnju rẹ̀ (Orin Dafidi 34:6)

O (Jesu) rán ọ̀rọ rẹ̀, o si mu wọn lara da, o si gbà wọn kuro ninu iparun wọn (Orin Dafidi 107:20)

Gẹgẹ bi ẹniti iya rẹ̀ ntù ninu, bẹ̃ni emi o tù nyin ninu; a o si tù nyin ninu (Isaiah 66:13).

Iwọ ki yio di ẹni-igbagbe lọdọ mi (Isaiah 44:21) Tọ́ ọ wò, ki o si ri pe, rere ni Oluwa (Jesu). (Orin Dafidi)

Jesu Kristi ọkanna ni li aná, ati li oni, ati titi lai (Heberu 13:8)

“Emi (Jesu) li ọ̀na, ati otitọ, ati iye: kò si ẹnikẹni ti o le wá sọdọ Baba, bikoṣe nipasẹ mi” (Johannu 14:6)

Nitori Ọmọ-enia (Jesu) de lati wá awọn ti o nù kiri, ati lati gbà wọn là(Luku 19:10).

Ṣugbọn iye awọn ti o gbà a (Jesu), awọn li o fi agbara fun lati di ọmọ Ọlọrun, ani awọn na ti o gbà orukọ rẹ̀ gbọ́ (Johannu 1:12).

Nitori ninu ẹkún rẹ̀ (Jesu) ni gbogbo wa si ti gbà, ati ore-ọfẹ kún ore-ọfẹ (Johannu 1:16)

Ṣugbọn a ṣá a li ọgbẹ nitori irekọja wa, a pa a li ara nitori aiṣedede wa; ìna alafia wa wà lara rẹ̀, ati nipa ìna rẹ̀ li a fi mu wa lara da (Isaiah 53:5)

“Emi ni oluṣọ-agutan rere: oluṣọ-agutan rere fi ẹmí rẹ̀ lelẹ nitori awọn agutan” (Johannu 10:11).

Ẹ ronupiwada; nitori ijọba ọrun kù si dẹ̀dẹ (Mattiu 4:17).

Gbà Jesu Kristi Oluwa gbọ́, a o si gbà ọ là, iwọ ati awọn ará ile rẹ pẹlu (Ise 16:31).

Eniti o ba si tọ̀ mi (Jesu) wá, emi kì yio ta a nù, bi o ti wù ki o ri (Johannu 6:37).

Nitori ti o fẹ ifẹ rẹ̀ si mi (Jesu), nitorina li emi o ṣe gbà a: emi o gbé e leke, nitori ti o mọ̀ orukọ mi (Orin Dafidi 91:14).

Bi mo (Jesu) ba si lọ ipèse àye silẹ fun nyin, emi o tún pada wá, emi o si mu nyin lọ sọdọ emi tikarami; pe nibiti emi gbé wà, ki ẹnyin le wà nibẹ pẹlu (Johannu 14:3).

Nitori ikú li ère ẹ̀ṣẹ; ṣugbọn ẹ̀bun ọfẹ Ọlọrun ni ìye ti kò nipẹkun, ninu Kristi Jesu Oluwa wa (Romu 6:23).

Nitori igbati awa jẹ alailera, li akokò ti o yẹ, Kristi kú fun awa alaiwa-bi-Ọlọrun (Romu 5:6).

 

Jesu Kristi Oluwa wa sinu aye yi ni nkan bii egbaa odun sehin. O nlo kaakiri lati soore fun gbogbo eniyan osi wo gbogbo oniruuru aisan san. O waasu ihinrere ni ti Ijoba Olorun. O ji dide ninu oku o si wa laaye loni. Oun kan na ni lana, loni ati titi lae. O nse rere fun gbogbo eni ti o ba to O wa koda titi di oni yi.

 

Adura:

“Jesu, mo feran Re, dari awon ese mi ji mi, ki o si wo gbogbo aisan mi san. Fun mi ni alafia, isinmi ati ayo. Fun mi ni iye ayeraye ki o si bukun fun mi. Amin.”

 

You can find equivalent English tract @

Jesus Loves, Jesus Helps