Famous Last words Yoruba

Famous Last words2 Yoruba

Oro kan ti o gbajugbaja ni orile ede wa ni pe, awon oro ikehin ti o lokiki, ti a saba ma nso ninu iyemeji, nkilo fun wa lati farabale ki a si maa reti ajalu kan ti o nilati sele. Sugbon lehin ti opolopo eniyan l’okunrin ati l’obinrin ba ti pari irin-ajo won laye, ti a gba iye kuro lowo won ti won si dojuko ayeraye, opolopo oro ikehin to ma ngunni l’okan lo ma njade lenu won. Awon kan le je eyi ti a so ninu idunnu ayo, ti awon kan si je eyi ti a so ninu ikoro ati eru nla gegebi olukore onroro na ti nde lati gba oun tii se tire.

Iku! Ohun ti ko see sa fun ti nfi opin si ete, erongba, ilepa, imo, alakale ero wa, abbl. O nsele si omode ati agba, olowo ati talaka, eni ide ati ominira, oba ati awon omo alade, titi o fi kan alagbe ti o wa ni opopo ona. Oro ikehin Olola Sir Thomas Smith tii se Akowe Agba julo ninu isejoba Obabinrin Elisabeti kinni ti ile Geesi ni odun1577, fi han wa gbangba pe asan ni lati gbe igbe aye wa fun aye yi nikan, o wipe:

“O je ohun ibanuje nla ki eniyan mase ni imo ohun ti eredi iwasaye eni je titi di igba ti o ba setan lati jade kuro ninu aye.”

Awon akojopo awon oro ikehin wonyi ni a ko ki oye ki o le ye olukawe yi kookan nipa idaniloju igbe aye lehin iku, ati bi ase le ni iye ainipekun nipase Omo Olorun, ani Jesu Kristi.  Bi akoko iku ba yi kan o, nje yio ba o leru ni, tabi oro ikehin re na yio dabi ti Catherine Booth, tii se aya Ogagun William Booth, eni tii se oludasile egbe Omo Ogun Igbala (Salvation Army), o wipe:

“Omi nkun soke, sugbon bee gege ni emi na, Emi ko ri sabe omi, sugbon mo duro lori re. Mase se aniyan nipa kiku, tesiwaju lati maa gbe igbe-aye rere, akoko kiku yio si dara.”

Nje o ni ilepa lati je oba, olori orile ede, tabi asaaju awujo nla? Kiyesi oro idagbere lati enu Oba Louis XIV, ti orile ede France, si omo re ni odun 1715:

“Omo mi, o see se ki nti gbe igbe aye ti o dara ju ti awon elomiran lo, keko ninu asise mi; ki o si maa ranti pe oba yio ku gegebi awon elomiran ti ma nku.”

Oba nku bi awon elomiran se ma nku!

Oba-nla Seferusi ti Ilu Romu (146-211A.D.), se aropo ti ainireti yi nipa igbe aye re, o wipe:

“Mo ti je ohun gbogbo, ohun gbogbo si jasi ofo. Igo kekere kan na ni yio gba eeru oku eni naa eniti gbogbo aye wa ni ikawo re.”

Oba Kalif Abd-Er-Rahman III ti Ilu Spain ni 961 A.D., ti ni iriri ofo ati ajalu aini idunnu:

Aadota odun lo ti koja lehin igba ti mo koko je oye Kalif. Oro, ola, igbadun aye, mo ti gbadun gbogbo re. Laarin awon akoko gbooro ti o farajo ti idunnu yi, mo ka iye ojo ti mo le so pe mo fi ni idunnu tooto, o je ojo merinla!

Bawo ni o se ri eyi si! Ninu aadota odun gegebi oba, o lo ojo merinla pere ninu idunnu.

Boya o je okan ninu awon ti o gba wipe ko si Olorun tabi awon ko tile fe mo boya O wa tabi ko si. Iru awon eniyan bi eyi a ma wa ona abayo kuro ninu ojuse won si Olorun nipa siso wipe Oun ko si. Won so ara won di “ope atinuda” nipa otito na pe “Nipa ọ̀rọ Oluwa li a da awọn ọrun, ati gbogbo ogun wọn nipa ẽmí ẹnu rẹ̀.” (O.D. 33:6). Okan ninu iru awon yi ni Voltaire, olokiki onimo ijinle ati alaigbagbo omo ile Faranse ti o gbe ni bii igba odun sehin (19th Century). Ni akoko kan, o so ni ti Kristi pe: “Ifibu ni fun olosi na.”

O tun fonnu nigba kan, o ni: “Ni ogun odun si akoko yi, ko ni si esin Kristiani mo. Owo mi nikansoso ni yio wo ile nla ti o gba awon aposteli mejila lati ko pale.”

Opin aye re banileru jojo, gbo ohun ti o wi: “Mo di eni ikosile lodo Olorun ati eniyan! Emi yio fun o ni idaji ohun ini mi bi o ba le fun mi ni osu mefa si laye, lehin eyi emi yio lo si orun apaadi, iwo na yio si lo pelu mi! Kristi, O Jesu Kristi!”

O seni laanu wipe, akoko oore ofe re ti koja tipe.

Thomas Paine je gbajugbaja olufe America ati alaigbagbo eniti o ko iwe oro odi ati atako bibeli kan ti a npe ni “Akoko Arojinle.” Igbe aye tire na fi opin ti o buru ti o si banileru han:

“Emi iba funni ni ni gbogbo aye, bi o ba wa ni ikawo mi, wipe ki a mase te iwe “Akoko Arojinle” jade. Oluwa o! ran mi lowo! Kristi! ran mi lowo! Olorun o! ki ni mo ha se ti mo fi njiya to bi eyi? Sugbon ko si Olorun! Sugbon bi o ba si wa, kinni yio ha sele si mi lehin ibi yi? E duro ti mi nitori Olorun! E ran bi o tile se omo kekere kan lati duro ti mi, nitori iriri orun apaadi ni lati da nikanwa. Bi esu ba tile ni asoju kan, emi ni eni na.”

Koda awon iranse Olorun kan, ni opin igbe aye won, ti beere nipa iwulo igbe aye won.

Thomas Wolsey, Alufa agba ti Ijo Katoliki ati agba oselu kan ni akoko isejoba Oba Henry VIII, so eyi lori akete iku re:

“Bi mo ba ti sin Olorun tokantokan bi mo ti se fun oba, Oun iba ti ko mi sile ni ojo ogbo mi. Sugbon eyi ni ere ti o to ti mo gbodo gba fun irora ati ikeko tokantokan  ti mo ti ni kin le sin I (oba), lai fiyesi ijosin mi si Olorun, bikose lati te ife oba lorun nikan.”

Se afiwe oro yi pelu oro ikeyin ti Matthew Henry, olokiki onimo nipa Olorun omo Geesi:

“Igbe aye ti a gbe ninu isin Olorun, ati ninu idapo pelu Re, ni igbe aye ti o ni iturajulo ti eniyan le gbe ni aye isisiyi.”

Bakanna Jonathan Edward, onisoji ati oniwaasu pataki ti o gbe ni nkan bi ogorun odun meta sehin, o ni ayo nla nigbati akoko re to. Eyi ni oro idagbere re: “Nibo ni Jesu wa, Ore mi ti ko kunna ri?”

Akosile awon oro ikeyin ko nii pe laisi oro awon ajeriku die, awon ti won ti yonda emi won nitori ti Kristi, awon ti ko ka emi won kun ohun ti o sowon fun won nitori ti ododo ati ihinrere. Polycarp je iru eni bee. Ajeriku ti o gbe ni nkan bi igba odun lehin iku Kristi, nigbati asoju ijoba Romu nilu re pase fun u ki o se Kristi ki o si soro odi si I, esi re niyi:

“Ogorin odun o le mefa ni o ti da nisisiyi ti mo ti nsin Kristi, Oun ko si tii se mi ni ibi kan ri bi o ti wu ki o mo, bawo ni emi yio se wa so oro odi si Oba mi ati Olugbala mi nisisiyi?”

Beeni a soo mo igi a si fi ina sun u laaye, oun ko se ohun kan ju wipe o yin Olorun fun ipamo re, igbala re, ati wipe O ka a ye lati je okan lara awon ajeriku.

Ogorun odun lehin eyi ni a tun ri okunrin kan ti a npe ni Andronicas, eniti, lehin ti won na a legba ti won si fi iyo ra oju ogbe na tan, won juu sodo awon eranko buburu ki won to fi ida paa. Eyi  ni oro ikeyin re:

“E se ife inu yin! Kristiani ni mi; Kristi ni iranlowo mi, Oun si ni alatilehin mi, ati pe bi a ti fi ihamora yi wo mi, emi ko ni sin orisa yin lae, beeni emi ko beru ase yin tabi ti oga yin, oba Romu: E bere iponniloju yin ni akoko ti e ba ti fe, ki e si lo gbogbo ona ti ero buburu inu yin le gba lati fi ponniloju, eyi yio si ri pe nikeyin e ko le si mi nipo kuro ninu ipinnu mi.”

Se afiwe awon wonyi pelu igbeyin okan ninu awon oninunibini ijo, Stephen Gardiner, Bisopu ti Winchester ni nkan bi egbeta odun sehin(16th Century). Eni yi ti o je ohun elo mujemuje ti ijo Katoliki ti akoko re, o ku nipase aisan bunuru kan pelu egun ni enu re:

“Mo ti dese bii ti Peteru; sugbon emi ko sokun bii tire.”

Lakotan, a ni oro ikehin ti Kristi. Ni ori agbelebu, ni okan idariji pipe fun awon to se inunibini si I, O gbadura:

“Baba, dariji won, nitori won ko mo ohun ti won nse.” Ni itewogba ironupiwada ti ole ori agbelebu ti wa legbe Re, O wipe,

“Loni ni iwo yio pade Mi ni Paradise.” Lehin ti o ti se gbogbo ife Olorun tan, O kigbe soke ni isegun:

“O pari.” Si Baba Re, pelu ekunrere igbekele ati ife O kigbe:

“Baba, ni owo Re ni mo fi Emi Mi le.”

Ore ti o nka oro yi, igbala re ni a ti ra ni kikun lori agbelebu nni ni nkan bii egberun meji odun sehin. Sugbon nibo ni igbe aye re nforile bayi? Bi o ba lo aadorin, ogorin, tabi aadorun odun laye, ere kinni yio je bi o ba jere gbogbo aye, sugbon ti o lo padanu emi re?

Jesu Kristi si nkanlekun okan re lowolowo. Nje iwo yio ronupiwada awon ese re loni, ki o si jowo aye re lati se ife Re? Abi se o ko ni je ki o ma joba laye re lati oni lo ati siwaju? Eyi nikan ni igbe aye ti o le fun o ni alaafia ati ifokanbale, nitori “ko si alaafia fun eniyan buburu, ni Oluwa mi wi.” (Isaiah 57:21)

“Nitori Ọlọrun fẹ araiye tobẹ̃ gẹ, ti o fi Ọmọ bíbi rẹ̀ kanṣoṣo funni, ki ẹnikẹni ti o ba gbà a gbọ́ má bà ṣegbé, ṣugbọn ki o le ni ìye ainipẹkun.” (Johannu 3:16)

Oluwa feran re, O si seleri iye ainipekun fun awon ti o ba to O wa

Fi aye re fun U loni!

Fun alaye kikun kan si: contact@sweethourofprayer.net

You can find equivalent English tract @

Famous last words