Parable of the Kingdom Yoruba

Owe ti Ijoba Na

“…, Ijọba ọrun si dabi àwọn, ti a sọ sinu okun, ti o si kó onirũru ohun gbogbo.

Nigbati o kún, eyi ti nwọn fà soke, nwọn joko, nwọn si kó eyi ti o dara sinu agbọ̀n, ṣugbọn nwọn kó buburu danù.

Gẹgẹ bẹ̃ni yio si ri nigbẹhin aiye: awọn angẹli yio jade wá, nwọn o yà awọn enia buburu kuro ninu awọn olõtọ, Nwọn o si sọ wọn sinu iná ileru; nibẹ li ẹkún on ipahinkeke yio gbé wà.

“Jesu bi wọn pe, Gbogbo nkan wọnyi yé nyin bi?” …” Mattiu 13: 47-51

“KINI KI EMI KI O SE KI N LE NI IGBALA?” Ise 16:30

  1. RONUPIWADA KI O SI GBA IHINRERE GBO

“O si nwipe, Akokò na de, ijọba Ọlọrun si kù si dẹ̀dẹ: ẹ ronupiwada, ki ẹ si gbà ihinrere                                    gbọ́!” Marku 1:15

  1. GBAGBO NINU JESU GEGEBI OLUWA ATI OLUGBALA RE

“Ṣugbọn iye awọn ti o gbà a, awọn li o fi agbara fun lati di ọmọ Ọlọrun, ani awọn na ti o   gbà orukọ rẹ̀ gbọ́.” Johannu 1:12

  1. JEWO AWON ESE RE FUN JESU

“Bi awa ba jẹwọ ẹ̀ṣẹ wa, olõtọ ati olododo li on lati dari ẹṣẹ wa jì wa, ati lati wẹ̀ wa nù       kuro ninu aiṣododo gbogbo.” 1 Johannu 1:9

  1. GBA IRIBOMI TI OMI ATI TI EMI MIMO

“Ẹ ronupiwada, ki a si baptisi olukuluku nyin li orukọ Jesu Kristi fun idariji ẹ̀ṣẹ nyin, ẹnyin                o si gbà ẹbun Ẹmi Mimọ́.” Ise 2:38

  1. GBE IGBE-AYE IHINRERE

“Pa ofin mi mọ́, ki iwọ ki o si yè; …” Owe 7:2

`TIRE NI LATI YAN !!!

“Bẹ̃ni idajọ rẹ yio ri: iwọ tikararẹ ti dá a.” 1 Oba 20: 40

Fun alaye kikun, jowo kan si: contact@aweethourofprayer.net

You can find equivalent English tract @

Parable of the Kingdom