Adehun Adojutofo ti Ofe ni gbogbo Re
Ilera
Ile
Ina
Emi
Ile-ise Adojutofo ti Ihinrere
Ilera
Iye owo fun itoju ara eni lodo awon onisegun ti di goboi, bee na ni iye owo eto adojutofo ti ILERA ko kere rara. Nje o ti se alabapade onisegun nla kan ti o so pe oun l’agbara lati ‘wo gbogbo arun re?’
“Ṣugbọn a ṣá a li ọgbẹ nitori irekọja wa, a pa a li ara nitori aiṣedede wa; ìna alafia wa wà lara rẹ̀, ati nipa ìna rẹ̀ li a fi mu wa lara da.” Isaiah 53:5
Ile
Awon Ile wa ni a ma nse eto adojutofo fun kuro lowo ohunkohun ti o le fa idibaje , ole, alejo ti a ko fe. Sibesibe awon irin idaboobo ti oju ferese ati ilekun, fere ti ntaniji bi ole ba de ati awon ode adugbo ko to lati fun awon onile ni aabo tabi ibale okan.
Ẹ maṣe jẹ ki ọkàn nyin dàru: ẹ gbà Ọlọrun gbọ́, ẹ gbà mi gbọ́ pẹlu. Ninu ile Baba mi ọ̀pọlọpọ ibugbe li o wà: ibamáṣe bẹ̃, emi iba ti sọ fun nyin. Nitori emi nlọ ipèse àye silẹ fun nyin” Johannu 14:1,2
Ina
Ina a ma jo ile ati awon dukia ti o se iyebiye, awon miran kii se mu pada bo sipo. Sugbon ninu ayeraye, ina kan wa ti yio ma jo titi ayeraye. Nje o ni eto adojutofo ti o le dabobo o kuro lowo ina na?
“Ẹniti o ba ṣẹgun ni yio jogún nkan wọnyi; emi o si mã jẹ Ọlọrun rẹ̀, on o si mã jẹ ọmọ mi. Ṣugbọn awọn ojo, ati alaigbagbọ́, ati ẹni irira, ati apania, ati àgbèrè, ati oṣó, ati abọriṣa, ati awọn eke gbogbo, ni yio ní ipa tiwọn ninu adagun ti nfi iná ati sulfuru jò: eyi ti iṣe ikú keji.” Ifihan 21:7,8
Emi/Iye
Opolopo lo nfi egbelegbe owo se eto adojutofo emi. Sugbon tani o ma ngba a? Kinni oke aimoye owo yi yio jamo fun o bi o ba ti ku tan?
“Nitori Ọlọrun fẹ araiye tobẹ̃ gẹ, ti o fi Ọmọ bíbi rẹ̀ kanṣoṣo funni, ki ẹnikẹni ti o ba gbà a gbọ́ má bà ṣegbé, ṣugbọn ki o le ni ìye ainipẹkun.” Johannu 3:16
Awon Amuye fun Eto Adojutofo na
- Mo ara re ni elese
“Gbogbo enia li o sá ti ṣẹ̀, ti nwọn si kuna ogo Ọlọrun” Romu 3:23
“Bi awa ba wipe awa kò li ẹ̀ṣẹ, awa tàn ara wa jẹ, otitọ kò si si ninu wa.” 1Johannu 1:8
- Mo wipe orun apaadi ni ere ese
“Ori awọn enia buburu li a o dà si ọrun apadi, ati gbogbo orilẹ-ède ti o gbagbe Ọlọrun.” O.D. 9:17
- Mo wipe o ko le fi agbara ara re gba ara re la
“Gbogbo wa si dabi ohun aimọ́, gbogbo ododo wa si dabi akisa ẹlẹgbin; gbogbo wa si rẹ̀ bi ewe; aiṣedede wa si mu wa kuro bi afẹfẹ.” Isaiah 64:6
- Gboran ki o si gboran si Olorun
“Pẹlupẹlu igba aimọ̀ yi li Ọlọrun ti foju fò da; ṣugbọn nisisiyi o paṣẹ fun gbogbo enia nibi gbogbo lati ronupiwada” Ise.17:30
- Gbagbo ninu Jesu Kristi gegebi Olugbala re
“Nitori Ọlọrun fẹ araiye tobẹ̃ gẹ, ti o fi Ọmọ bíbi rẹ̀ kanṣoṣo funni, ki ẹnikẹni ti o ba gbà a gbọ́ má bà ṣegbé, ṣugbọn ki o le ni ìye ainipẹkun.” Johannu 3:16
- Jewo awon ese re fun Jesu
“Bi awa ba jẹwọ ẹ̀ṣẹ wa, olõtọ ati olododo li on lati dari ẹṣẹ wa jì wa, ati lati wẹ̀ wa nù kuro ninu aiṣododo gbogbo.” 1Johannu 1:9
- Gba Iribomi ti Omi Ati Emi Mimo
“Peteru si wi fun wọn pe, Ẹ ronupiwada, ki a si baptisi olukuluku nyin li orukọ Jesu Kristi fun idariji ẹ̀ṣẹ nyin, ẹnyin o si gbà ẹbun Ẹmi Mimọ́.” Ise 2:38
- Gbe Igbe-Aye Ihinrere
“Ṣugbọn ki ẹ jẹ oluṣe ọ̀rọ na, ki o má si ṣe olugbọ́ nikan, ki ẹ mã tàn ara nyin jẹ.” Jakobu 1:22
Eto Adehun Naa
A se adehun yi fun ayeraye. Ko si iye owo tabi ise rere ti o le san iye re. A ti san gbogbo iye owo re nipase Jesu Kristi nigbati O ti ku lori igi agbelebu. Gbogbo ohun ti o je mo owo idojutofo, owo ajosan tabi ofo ajopin ti o je mo adehun yi ni Jesu ti san nipa iku Re lori agbelebu. Eto idojutofo yi ni a fi fun gbogbo eniyan lofe nipa Oore-ofe Re (Efesu 2:8). O duro lori igbagbo ti o duro sinsin ninu Jesu Kristi (Efesu 3:17)
You can find equivalent English tract @