17 / 100

God loves you Yoruba12

Download PDF Tracts

OLORUN FERAN RE

Nje o mo eni na ti o feran re julo? Eni naa ni Olodumare, Olorun, Eleda wa (Ifihan 1:8;Genesisi 1:26,27; 2:7). Olorun ayeraye yi feran re lopolopo de ibi wipe O ran Jesu Kristi, Omo Re kansoso, lati ku lori igi agbelebu, ki a le dari awon ese re ji o. (Luku 23:34).

Nje o mo idi ti Olorun se fe o tobee? Nitori O je Olorun ife Eniti o da o ni aworan ara Re. Emi re ko le ku lailai o si se iyebiye si Olorun ju gbogbo aye lo (Mattiu 16:26).

Olorun feran re sugbon o korira ese O si gbodo se idajo ese. Ese ma nmu ibanuje nla ba okan Olorun; o ma nyani nipa kuro lodo Re. Ni ojo idajo, Kristi yio so fun elese pe, “Ẹ lọ kuro lọdọ mi, ẹnyin ẹni egun, sinu iná ainipẹkun, ti a ti pèse silẹ fun Eṣu ati fun awọn angẹli rẹ̀”: “…ṣugbọn awọn olõtọ si ìye ainipẹkun.” (Mattiu 25:41,46).

Nitoripe Adamu akoko se aigboran si Olorun, ese, egun,aisan, ati iku wo inu aye; gbogbo wa di elese, a si di eni idalebi si inu ina ayeraye ninu orun apaadi. Sibesibe Olorun si feran omo eniyan, eyi ti oun ti da, ati ti o si ti rapada nipa iku Kristi, ti o si da gbogbo ibukun eyi ti Adamu ti sonu  nipase ese ati aigboran re pada fun won (Romu 5:1-21;Efesu 1:3-14).

Jesu ku ni ipo re ki a ma ba da o lebi, sugbon ki iwo ki o le ye pelu Olorun titi aye ainipekun bi iwo ba le fi igbekele re sinu re. “Nitori ikú li ère ẹ̀ṣẹ; ṣugbọn ẹ̀bun ọfẹ Ọlọrun ni ìye ti kò nipẹkun, ninu Kristi Jesu Oluwa wa.” (Romu 6:23)

Iwo le ri bi Olorun ti fe o to. Ko ran okan ninu awon angeli Re lati gba o la, sugbon o ran Omo bibi Re kansoso si inu aye lati gba o la nitori o feran re. Jesu wipe “Nitori Ọlọrun fẹ araiye tobẹ̃ gẹ, ti o fi Ọmọ bíbi rẹ̀ kanṣoṣo funni, ki ẹnikẹni ti o ba gbà a gbọ́ má bà ṣegbé, ṣugbọn ki o le ni ìye ainipẹkun.” (Johannu 3:16). Sibesibe Olorun je mimo ati olooto. Ayafi bi o ba ronupiwada ti o si gba etutu Kristi fun ese re ni yio to gba o. (Johannu 3:3;Romu 3:24-26). Jesu wipe “Ronupiwada, ki o si gba ihinrere gbo”(Marku 1:15).

Nitorina, ronupiwada, gbagbo pe Jesu Kristi nikan ni o ku fun ese re ki o si gba A sinu okan re gegebi Olugbala ati Oluwa re. Dajudaju Olorun yio we gbogbo ese re nu ninu eje Jesu yio si so o di alailabawon. Emi Mimo yio yi aye re pada yio si fun o ni okan titun nigbati iwo ba ngbo oro Re ti o si ngboran si i. Oun yio so o di mimo, yio fi ife, ayo ati alafia, ogbon ati agbara kun o, yio si ma to o sona lati ma gbe igbe aye re fun ijoba Re.

Ore mi owon, gboran si Oro Olorun Olodumare Eni na ti o feran re. Ronupiwada ki o si yipada si Olorun nisisiyi. Igbe aye kansoso ni o ni lati gbe, o le ku lojiji; iwo ko mo igba tabi ona ti yio gba sele. Sugbon Olorun ninu aanu Re ti fun o ni anfani lati murasile fun ayeraye. Laisi idariji Olorun, inu adagun ina ni a o ju o si “nibiti okan re ki yio kú, ti iná na ki si ikú.” (Marku 9:47,48).

Ko si ironupiwada lehin iku, bikose idajo Olorun (Heberu 9:27). Jesu Kristi ni ajinde ati iye. Oun yio ji o dide kuro ninu oku yio si se idajo re gegebi ise re ba ti ri. (Johannu 11:25; Johannu 5:24-29). Ronu ki o sigbe igbese nisisiyi. Ni akoko iku, iwo yio fi oju rinju pelu Olorun, idajo Re ati ayeraye!

Gba wipe o je elese. O nilo Olurapada, Jesu Kristi Oluwa, Eni na ti o le gba o la kuro ninu ese re lati bo kuro ninu ibinu ati idajo Olorun ti o mbo. Beere fun idariji ese re lodo Olorun nisisiyi nipa gbigba awon adura yi si I tokantokan re

ADURA

“ Olorun mi owon, dariji mi, emi elese, eni ti o ye lati ku iku ti Jesu gba ku. Mo kaanu fun gbogbo awon ese mi mo si yipada si O loni. Mo jewo mo si gbagbo wipe Jesu Kristi Omo bibi Re kansoso, ni Eni ti o jiya ti o si ku lori agbelebu, ti a sin ti o si tun ji dide lati ra mi pada. Jowo we mi pelu eje Jesu ki o si so mi di omo Re. Mo pe Jesu wa sinu okan mi gegebi Oluwa ati Olugbala aye mi. Ranmilowo lati gbe igbe aye mi fun o lati oni lo. E seun Baba mi fun gbigba okan mi la ni oruko Jesu! Amin.

 

Iru anfani wo lo to eyi lati je omo Olorun alaaye! Ope ni fun Jesu fun igbala re ni gbogbo ojo.

 

 

You can find equivalent English tract @

God Loves You