BI O SE LE NI IDUNNU (AYO) TOOTO
Jowo mase so iwe ilewo yi nu titi di igba ti iwo yio ka a tan. Jesu le yi aye re pada ki o si fun o ni ona abayo si awon isoro re. Dajudaju, o seese ki o ti maa daamu kiri lati se awari ibale-okan ati idunnu, ti iwo ko si tii ri i. Egbeegberun ni o ti daamu lori asan lati ni ibale-okan ati idunnu nipase siga-mimu, oti-mimu, ijo, tete-tita, lilo egboogi oloro ati fifi ara won ji fun pansaga ati agbere. Dipo ki won ri idunnu, won ba ara won ninu igbekun irora idaamu okan ati aisan. Awon miran ninu ipo ainireti a tile gba emi ara won. Ore mi owon, asiri idunnu tooto si wa rorun pupo. Ni awon odun die sehin, mo je eniti idaamu okan fere yi ni opolo nipase igbe aye ese ti mo ngbe. Mo gbiyanju lati se awari idunnu nipa opolopo esin, eyi ti esin Kristiani je okan ninu re, sugbon pabo lo ja si. Mo to opolopo awon eniyan pataki awujo ati awon elesin lo. Mo ka opolopo awon iwe ti o nkoni ni iwa rere ati ti omoluabi eyi ti a ti owo awon eni nla kaakiri agbaye ko. Abayori gbogbo re ni idaru okan ati rudurudu. Nigba miran, gbogbo ile aye a tile su mi. Ni ojo kan gbogbo aye mi sa dede yipada lona ara. Ojo na ni ojo ti Jesu Kristi fi ara han mi ti o si so fun mi wipe Oun ti ku fun ese ati arun mi ati wipe bi mo ba le gba oun gbo ti mo si jewo ese mi fun Oun, Oun yio dari ji mi, yio si yi igbe aye osi ati eeri ti mo ngbe pada. Mo sokun si Jesu lati isale okan mi. Lesekese bi mo ti beere fun idariji gbogbo awon ese mi, eje iyebiye na ti O ta sile lori agbelebu Kalfari we mi mo. Mo wa ni imolara ifokanbale nla. O wa dabi eni wipe egbegberun awon oke to ga ju laye (Himalaya) ti o ti nrin mi mole ni a ti si nidi ti o si poora. Imolara ti o tuni lara: “Alafia ti o ta oye gbogbo yo,” ti o koja apejuwe enu eniyan, rin gbogbo iseda mi ja. Bi ayo orun ti ru bo aye mi bi omi pupo ti o si rin okan mi ja, mo ni iriri Kristi ti o nwole sinu okan mi ti o si ngunwa gegebi Oba awon oba ati Oluwa awon oluwa. Lati igba na, mo ri wipe igbe aye mi ti ni itumo titun. O ti tun wo mi san kuro ninu awon aisan buburu bii, atogbe, iko fere, opa ehin riro, iba jedo-jedo ati ti ponju-ponto. Nisisiyi nipase Jesu Kristi Oluwa, emi na di eni ti o ni idunnu ati ilera. Loni iwo na le gbadun gbogbo nkan wonyi ati opolopo iriri ti o tun yanilenu miran, bi iwo yio ba gba Jesu Kristi ni lowolowo yi gegebi Olorun ati Olugbala re ki o si jewo ese re fun U. “Bi awa ba jewo ese wa, olotito ati olododo ni Oun lati dari ese wa ji wa, ki o si we wa kuro ninu aisododo gbogbo.” “Eje Jesu Kristi … nwe wa nu kuro ninu ese gbogbo.” Bakanna bi o ba ni aisankaisan, yala ti ara tabi ti okan, O le wo o san ki o si fun o ni ilera ati idunnu. “Ṣugbọn a ṣá a li ọgbẹ nitori irekọja wa, a pa a li ara nitori aiṣedede wa; ìna alafia wa wà lara rẹ̀, ati nipa ìna rẹ̀ li a fi mu wa lara da.” (Isaiah 53:5).” (Jesu) wo gbogbo awon ti o saisan san.”
Nisisiyi, jowo gbadura: “Jesu Oluwa, mo gbagbo wipe iwo ni Olorun ati Olugbala mi. Iwo ku fun gbogbo ese ati arun mi. Dariji mi ki o si fi eje iyebiye Re we gbogbo ese mi nu. Wa sinu okan mi. Gba mi ki o si wo mi san nisisiyi. Ni Oruko Jesu Amin:” “Enikeni ti o ba gbekele OLUWA (JESU), o ni ayo.”
You can find equivalent English tract @