ENI NA TI O FI EMI RE LELE FUN O
Olorun da eniyan ni aworan ara Re. Eniyan ni ibasepo pelu Olorun, o ni alafia ati ayo ninu okan re ati ilera ti o peye ninu ago ara re. Sugbon nigbati o dese, o padanu ajosepo ti o ti ni pelu Olorun, o so alafia ati ayo ti o wa ninu okan re nu, ibanuje wa de ba a, o di ije fun aisan ninu ago ara re, o si di alainisinmi ninu emi, okan ati ara re. Lati ra iran eniyan yi pada ki a si da ohun gbogbo ti o ti padanu pada fun u, a bi Olorun Eleda wa si inu aye yi pelu eran ara ati eje, a si pe oruko re ni Jesu, eyi sele ni nkan bii egberun meji (egbaa) odun sehin. A bi I laini ese. O gbe igbe aye ailese ninu aye ese yi, o si lo kaakiri awon ileto ati ilu nla lati se rere fun awon eniyan. O mu ki afoju riran, o mu ki aditi gboran, o mu odi soro, o wo awon adete san, o tu awon ti emi esu nyolenu sile, o si waasu fun awon otosi.
Ko si imukuro ese laisi itajesile. Gegebi ofin ti la a kale, eyiti o so wipe, nipa eje ni a le se etutu fun okan, Jesu Oluwa wa pinnu lati ta eje Re sile fun gbogbo iran omo eniyan o si yonda ara Re lati ku lori agbelebu. Awon omo ogun Roomu fi iya je E yanna yanna; won hun ade egun le E lori; won si lu U pelu ogo ati egba. Lehinna ni won kan A mo agbelebu ti won si gbe E ko pelu eso meta.
Jesu Oluwa ti ko mo ese kankan ri, Eni ti ko dese ti ko si si ese kankan ninu Re, ni a sa logbe fun irekoja wa. A pa A lara nitori aisedede wa. Ijiya ti o mu alafia wa fun wa ni o wa lori Re. Iku ni ere ese. Jesu Oluwa funra Re gba iya ti o ye ki iran eniyan je nitori ese re je, o si ku lori agbelebu.
“Ṣugbọn Ọlọrun fi ifẹ On papa si wa hàn ni eyi pe, nigbati awa jẹ ẹlẹṣẹ, Kristi kú fun wa”(Roomu 5:8) Jesu Oluwa ko ku lori agbelebu nikan, sugbon gegebi O ti so tele, O segun iku ati orun apaadi O si ji dide ni ojo keta. Oun na ti o ji dide, ni o goke lo koja awon orun ti O si tun wa laaye fun wa.
Ore owon! Bi o ba le ronu jinle lori awon iya ati irora ti Jesu je nitori re, okan okuta re yio yo. Bi o ba si le wa fi omije beere fun idariji ese ati irekoja re, Oun yio dari ji o yio si fun o ni alafia, ayo ati isinmi. “Ejẹ Jesu Kristi Ọmọ rẹ̀ ni nwẹ̀ wa nù kuro ninu ẹṣẹ gbogbo … Bi awa ba jẹwọ ẹ̀ṣẹ wa, olõtọ ati olododo li Oun lati dari ẹṣẹ wa jì wa” (1Johannu 1: 7-9).
Jesu Kristi ku lori agbelebu kii se fun ese wa nikan, sugbon fun aisan wa pelu. “On tikararẹ̀ gbà ailera wa, o si nrù àrun wa” (Mattiu 8:17). “Nipa ìna rẹ̀ li a fi mu wa lara da”(Isa. 53:5).
Nitori ese eniyan, egun wa ati nitori egun na, aisan wa sori re. Jesu Oluwa ru awon aisan wa lori agbelebu. Bi a ba gbagbo wipe a wo wa san nipa ina Re, a le ye nipa gbigba itusile pipe kuro ninu awon aisan wa.
Ore owon! Bi iwo ba gbagbo wipe Jesu Oluwa ti o fi emi Re fun o ni a ti ji dide ti o si wa laaye fun o, o le gba itusile kuro lowo awon ese ati aisan re nipa eje Re. Jesu npe o pelu ife lati gbe igbe aye mimo ki o le wo orun rere.
Bi o ba fe lati ni awon ibukun ti o tayo eyi ti a ngba nipase iku Jesu Oluwa, gba adura wonyi:
“Jesu Oluwa, mo gbagbo wipe Iwo fi emi Re fun mi lori agbelebu ti Kalfari fun awon ese mi. Jowo dari awon ese mi ji mi. We mi ki o si ya mi si mimo nipase eje Re. Mo gba O gegebi Olugbala ati Olorun mi. Lati isisiyi lo n o ma gbe aye mi gegebi omo Re, Amin.”
You can find equivalent English tract @