NIBO NI IWO YIO TI LO AYERAYE RE?
Itan kan so nipa ojogbon onimo ijinle kan ti o rin irinajo lo si igberiko sugbon ti o sonu. O wa de orita merin kan nibiti o ti pade omodekunrin kekere kan ati aja re, o bii wipe “Omo, nibo ni ona yi ja si?” “Emi ko mo” omode na dahun. “Nibo ni ona eyi lo ni tire?” “Emi ko mo.” “Ati Iyen naa?.” “Emi ko mo.” “Ati eyi?” Emi ko mo.” Okunrin na wa pariwo pe “Iwo oponu omo yi, ko tile mo ohun kankan!” Omo na wa da a lohun wipe “O dara, ohun kan ni mo mo. Emi ko sina bi tire!”
Ore, ayeraye kan nbe niwaju re. O ntesiwaju lo sinu iye ainipekun tabi idalebi ayeraye, okan ni yio jasi tabi ekeji. Bibeli wipe, “Wakati mbọ̀, ninu eyiti gbogbo awọn ti o wà ni isà okú yio gbọ́ ohùn Rẹ̀ (Jesu). Nwọn o si jade wá; awọn ti o ṣe rere, si ajinde ìye; awọn ti o si ṣe buburu, si ajinde idajọ. (Johannu 5: 28,29). Nje o mo ibiti iwo nlo? Nje iwo mo ibiti iwo yio ti lo ayeraye re? Gegebi Ojogbon inu itan yi, o le ni imo nipa opolopo nkan ninu aye yi ati nipa re; sugbon sibesibe, o seese ki o ma mo ibi ti o nlo lehin iku.
A ko le sa fun igbe aye lehin iku; sugbon a le yan ibi ti a o lo nibe. Oluwa wipe, “Emi fi ìye ati ikú, … siwaju rẹ: nitorina YÀN ÌYE” (Deuteronomi 30:19).
Nisisiyi, bayi ni o sele mo ibi ti o wa, ati ibi ti o nlo, o le see se ki o fe yi ibi ti o nlo pada.
Okan ninu agbegbe meji ti o wa ninu igbe aye lehin iboji ni Orun rere tabi Ijoba Olorun. O je ile ti o kun fun imole ati ewa, ile alafia ati ayo pipe. O je igbe aye gbigbe niwaju Oluwa ati gbigbadun gbogbo adun ti o ti pese sile fun wa. Eniyan lasan ko le mo ohun gbogbo nipa re, nitori, Bibeli wipe, “Ohun ti oju kò ri, ati ti etí kò gbọ, ti kò si wọ ọkàn enia lọ, ohun wọnni ti Ọlọrun ti pèse silẹ fun awọn ti o fẹ ẹ.” (1Korinti 2:9). Ta wa ni eni naa ti o le mo asiri Ijoba Olorun “Oluwa ọrun on aiye, nitoriti iwọ pa nkan wọnyi mọ́ kuro li oju awọn ọlọ́gbọn ati amoye, iwọ si fi wọn hàn fun awọn ọmọ-ọwọ́,” ni Oro Olorun wi. (Mattiu 11:25), Awon “Omo owo” wonyi na ni o si le wo Ijoba Olorun (Mattiu 18:3). Nitorina ore mi owon, bi iwo ba le sokale ni ibi giga ti o fi ara re si ti o si fi irele yipada si odo Jesu Oluwa, iwo yio ri awon ohun nla ti a ti pese sile fun o ninu ayeraye; Oluwa yio si tun fi ona han o de ibe.
Ile miran ti o tun wa ninu ayeraye ni Orun Apaadi. O je ibi okunkun ati ikoro ni ibi ti a o ti maa je awon ti o ko Jesu Oluwa niya titi laelae. Ibi yi ni a pese sile fun esu ati awon angcli re nitori iwa won; iwa buburu won ni o se okunfa “ina orun apaadi” (Mattiu 25:41). Omo eniyan naa yio ni ipin ninu re pelu esu, nigbati o ba ti yan lati tele esu, nigbati o ba nrin “gẹgẹ bi ipa ti alade aiye yi, gẹgẹ bi alaṣẹ agbara oju ọrun, … a nmu ifẹ ara ati ti inu ṣẹ” (Efesu 2:2,3). “Ẹ̀ṣẹ ẹni-buburu ni yio mu ontikararẹ̀, okùn ẹ̀ṣẹ ara rẹ̀ yio si dì i mu.” (Owe 5:22). Orun Apaadi na ni a tun npe ni “Iku” (Ifihan 21:8) O je “ere” ti ese nsan fun eniyan (Romu 6:23). Nini ero ti ara je “iku” (Romu 8:6); gbigbe ninu adun ese je “iku” (1Timotiu 5:6) diedie ni Iku ngbe o mi!
Jesu Oluwa sokale lati ta eje re sile fun wa ki awon ti o ba gbagbo ninu Re ti won si gba A gbo le bo kuro ninu ibi inira ayeraye yi ki won si ni iye ainipekun. Oun ni ona, otito, ati iye (Johannu 14:6). “Ẹniti o ba gbà Ọmọ (Jesu) gbọ́, o ni iye ainipẹkun: ẹniti kò ba si gbà Ọmọ gbọ, kì yio ri ìye; ṣugbọn ibinu Ọlọrun mbẹ lori rẹ̀” (Johannu 3:36).
Olukawe mi owon, dase duro ni oju ona ti o nto. Beere lowo ara re; “Nibo ni mo nlo? Ibo ni mo ma ja si lehin iku?” Ri I daju loni wipe ona otito ni o nrin.
ADURA: Jesu Oluwa mi Owon, mo gba O gegebi Oluwa ati Olugbala mi. Jowo wa sinu okan mi. We gbogbo ese mi nu ki o si je ki nye fun Orun rere (Iye Ainipekun). Amin.
AKIYESI PATAKI: Akainiye agbegbe ni o wa ninu Ijoba Ainipekun ti Olorun eyi ti o kun fun ogo ati ewa otooto.
You can find equivalent English tract @