19 / 100

The Amazing Grace of God Yoruba111The Amazing Grace of God2 Yoruba

Download PDF Tracts

 

OORE OFE OLORUN TI O YANILENU

Nigbati mo fi ma di omo odun merinla, mo ti di ogbontagi omuti paraku mo si ti ngbe igbe aye idibaje ati isekuse ti eniyan le lero re. Mo bere nipa fifi sibi mu oti lile titi de mimu galonu marun lojumo! Laisi itodagba ti o nitumo tabi eko igbe aye Kristiani, emi ati awon arakunrin mi dagba gegebi ehanna eranko. Satani, ‘omo alade aye yi,’ fo mi loju mo si ngbe igbe aye abosi, imotara eni nikan, aiwabi Olorun ati iparun. ‘Ona kan wa ti o dabi eni wipe o dara loju eniyan; sugbon opin re je ona iku.’

Nigbati mo fi ma di omo ogbon odun, igbe aye ese mi ti wa de gongo. Ni oru ojo kan, mo de sinu ile pelu yiyo fun oti, mo bere si ba awon ti won ngbe pelu mi se ohun aso. Won hale mo mi eru si bere sii ba mi. Esu, eni na ti o wa ‘lati jale, lati pa, ati lati parun,’ gbo mi laya lati fi ibon ilewo .38 caliber mi pa awon mererin. Lehin ti mo ti yin won nibon tan ni o wa so fun mi wipe ki npa ara mi, mo yin ara mi niiki ibon maarun: meji ni ikun, okookan ni ogangan edo foro kookan, ati okan ti o ku ni agbari mi.

Lojiji, imole nla kan tan yi mi ka mo si gbo ohun efufu lile nla kan ti o nbo wa si odo mi. Gegebi lori ero mohunmaworan, Emi Olorun sipaya gbogbo awon ese mi fun mi koda lati igba ewe mi wa. O wa ye mi wipe elese ti o ti sonu ti o si nlo si orun apaadi lowolowo ni mi ‘iku ni ere ese’ mo le ni imolara ina orun apaadi ti o njo ninu okan mi. Nigbana ni Emi na wa wipe: ‘Enikeni ti o ba pe Oruko Oluwa ni a o gbala. Pelu ibon ti sin se eefin ni owo ati eje ti o nsan jade lara mi; mo ta gbongbon lo sinu okunkun oru oganjo mo si npariwo wipe, ‘Jesu Oluwa gba mii!’

Lojukanna; ohun ara oto bere si i sele oye wa bere si ye mi nipa ijagun ti o nlo lowolowo laarin awon angeli Olorun ati awon emi esu. Emi Olorun  ba le mi bi ina ti njo, o si nle awon emi aimo ti oti-mimu, siga-mimu, pansaga, oro-odi, abbl jade lo. Eje Jesu we mi mo kuro ninu awon ese wonyi, Alafia ati ayo nla ro wo inu aye mi bi isan omi. Mo ti di ‘atunbi’ gegebi omo Olorun mo bo kuro lowo igbekun agbara Satani. Lehinna ni Jesu kun mi fun Emi Mimo ati ohun iyin orun ninu ede aimo titun ti o nti enu mi jade! Ninu ipo ifarapa ti mo wa mo ta gbongbon siwaju mo si subu lule lailagbara sori oju ona oko oju irin kan. Otutu bere si dabo mi ti eje si and jade lara mi; lojiji, si iberu nla fun mi, mo ri oko oju irin kan ti o mbo! Esu ngbiyanju lati pa mi, sugbon Oluwa gba mi ni ona iyanu nipa riran olopa kan ti o fi asia owo re da oko oju irin na duro. Olopa na fi siga si mi lenu lati mu, sugbon nisisiyi, fun idi ti o sajeji si mi,  o jo ohun ti o je aimo lara mi. Olorun ti tu mi sile patapata kuro ninu gbogbo iwa buburu inu mi o si fun mi igbe aye titun. Bawo ni ore ofe igbala Olorun ti yanilenu to!

Lehin ti won gbe wa de ile iwosan, gbogbo akitiyan lati lati gba emi wa la ni o ja si pabo won si pa wa ti lati ku. Sugbon sibe, Oluwa ran awon Kristiani die wa lati gbadura fun wa awa maraarun si gba iwosan lesekese. Jesu kii se Olugbala okan nikan bikose Oluwosan ara pelu. ‘Jesu le awon emi aimo jade pelu Oro Re, O si mu awon alaisan larada… ‘ati wipe’… nipa ina Re ni a mu yin larada.’ Ona Olorun je pipe o si koja oye eniyan. O nse itoju awon eye ologose keekeeke, melo melo wa ni awon ti won yipada si odo Re.

Jesu Kristi wa di Olugbala mi, Oluwosan mi, ati lehinna, o wa di ‘Agbejoro’ mi pelu. Ni ojo igbejo mi ni ile ejo, mo duro laisi eniti yio gba ejo mi ro niwaju adajo. Ohun gbogbo wa dide tako mi, sugbon Olorun fi owo to okan adajo o si kede ewon ogun odun pere fun mi. Bi o tile je wipe mo nilati lo akoko pipe yi ninu ogba ewon, okan mi ni ominira gegebi eye nitori Olorun ti yi aye mi pada lona ti o ya ni lenu. ‘Enikeni ti o ba dese di eru ese… Bi omo ba so yin di ominira eyin yio di ominira nitooto.’

Oungbe kan wa kun inu okan mi lati mo si nipa Jesu, mo wa gbadura si Olorun lati ran mi lowo ni gbogbo akoko ti mo ma lo ni ogba ewon. Bi mo se nwo inu yara mi ni ogba ewon fun igba akoko, Emi Mimo so fun mi wipe ki nwo abe ibusun mi. Nigbati mo ma wo abe timutimu ibusun mi, si iyalenu nla fun mi, mo ba Bibeli titun yanran yanran. Halleluyah! Isoro kan  ti o tun wa wa nibe ni wipe mi ko tii ko bi won ti I ka iwe ri; sugbon Olorun, ti o nse ohun gbogbo daradara, bere si I ko mi lojoojumo.

Nibiti mo ti nka Oro Olorun, mo ri ibi ti Saulu, Farisi Juu kan, ti ri iriri iyipada ti o yanilenu pelu. Saulu na, gegebi awon eniyan kan loni, ko gbagbo pe Jesu je Omo Olorun, ani Mesaya na. Nitorina, ninu itara esin ti o ni o se inunibini si, o si pa opolopo awon Kristiani ni igba aye re. Sibe Olorun eniti o po ni aanu, tun le gba iru eniyan  bi eleyi la. Mo tun ka pe ni ojo keta lehin iyipada re, Saulu (eni ti a mo si Paulu nisisiyi), se iribomi ti omi lehin eyi ni Olorun kun u pelu Emi Mimo. Nitorina, niwon igba ti iru iriri yi ko I tii farahan ninu iyipada temi, mo finufindo gboran si Oluwa nipa gbigba iribomi ti omi ni igba akoko ti mo ni anfani re.

Ninu ogba ewon mo gbo opolopo iwaasu lori redio mo si kowe beere fun awon idanileko Bibeli nipa ifiweranse, sugbon bi mo tin ka awon iwe ilewo wonyi ni gbogbo re tun ndaru mo mi loju sii. Nigbana ni Olorun wa so fun mi ki nba awon iwe na je ki Oun le ma ko mi lati inu iwe Re, Bibeli funra Oun. ‘Nigbati Oun, ani Emi Otito ni ba de, Oun yio ma to yin sinu otito gbogbo’ ati wipe eyin ko nilo ki enikeni ko yin mo … ifamiororo yan kan na yio ma ko yin ni ohun gbogbo … ‘ Oro Olorun wa di idunnu mi t’osan t’oru. Gegebi orisun itunnu, agbara ati itoni, Oro Re je ki nle gbe igbe aye mimo ati ti isegun ni gbogbo odun ti mo lo ni ogba ewon.

Nipa irunisoke ife Kristi, pelu awon Kristiani ti o ku, a bere si jeri fun awon elegbe wa ninu ewon, lati koni ni eko Bibeli, ati lati gbadura fun awon alaisan. A la opolopo inunibini koja, ni opo igba ti o je mo ki a fi emi wa wewu sugbon a tesiwaju lati ma gbe Oruko Jesu Kristi ga ti a sin yin I logo.

Lakotan, lehin nkan bi odun metala, nipa awon iwa rere ti a ri laye mi, a tu mi silekuro ni ogba ewon. Lehinna, gegebi a ti dari Peteru lo si odo awon eni mimo aladura lehin itusile re kuro ninu ewon. Oluwa dari mi lona iyanu  si odo awon egbe aladura perete kan ti won ti ko gbogbo re sile lati sin Olorun. Laipe lehin eyi, mo fi gbogbo igbesi aye mi ji pata fun Eni na ti o fi ara Re fun mi lori igi agbelebu. Ni opo igba o ma nje iyalenu fun mi, ti n o si bi ara mi leere pe, ‘Kin lo de ti o fi je alainilaari bii temi ni Olorun wa yan fun ise Re?’ ‘Olorun ti yan ohun ope aye yi lati daamu ologbon; O si ti yan ohun alailera ti aye yi lati daamu awon alagbara; awon ohun ti ko nilaari ni aye ati awon ohun ti a ko naani, ni Olorun yan, ani, awon ti ko si, lati so awon ohun ti o wa di ofo, ki eran-ara kan ma baa sogo niwaju Re.’ Nitooto a mu Oro Re se!

Ore mi, bi Olorun ba le gba elese bi iru ti emi la, O le gba o la, O le gba enikeni la. Eje Jesu ti a ta sile lori agbelebu fun ese gbogbo aye si lagbara sibe lati se iwenumo, itusile, ati igbala fun elese yi o wu ti o ba to O wa tokantokan. Kin lo nda o duro lati jowo aye re fun U loni? Jesu Kristi mbo laipe! O le ran o lowo lati gbe igbe aye mimo ati ti isegun ki o le setan fun ojo na.

Bi gbogbo aye tile je temi,

Ebun kekere julo ni eyi je;                                    

Ife orun alailegbe,

Beere fun aye mi, okan mi, ohun gbogbo ti mo ni!

 

Lati isisiyi lo, ‘fun mi lati wa laaye ni Kristi, ati lati ku!’

A gba mi la lati sin I, Samuel Drain

 

ADURA: Baba, Mo Ronupiwada kuro ninu ese mi gbogbo (jewo awon ese re ni ekunrere). Dariji mi, ki O si fi Eje Omo Re, Jesu Kristi we mi. Fi Emi Mimo Re se edidi mi ki o si mu mi setan fun bibo Kristi laipe; ni oruko Jesu. E seun Oluwa! Amin.

 

IBI KIKA NINU BIBELI: Owe 14:12; Johannu 10:10; Romu 6:23; Romu 10:9-13; Johannu 3:3-5; Ise 2:1-4; 1Kor. 14:2;14:18; Mat. 8:16.17; 1Pet.2:24; Johannu 8:34,36; Ise. 9:1-20; Johannu 16:13; 1Johannu 2:27; Ise 12:1-17; Luku 14:26-33; 1Kor.1:26-29; Filp. 1:21.

 

You can find equivalent English tract @

The Amazing Grace of God