NJE A TI FI ORUKO RE SILE?
Nigbati a bi o si aye, awon obi re fi oruko re sile ni ile-ise iforukosile fun awon ti a bi ati awon ti won ti ku. Siwaju si, opolopo awon ibi miran ninu aye ni a tun ti fi oruko re sile, fun apeere,
- Nigbati a gba o si ile-iwe
- Nigbati a sese gba o sise
- Nigbati o ra ile ati ile kiko
- Nigbati o se eto adojutofo fun moto re
- Nigbati o gba iwe ifowopamo
- Nigbati o gba iwe ounje
- Nigbati o gba iwe idibo
- Nigbati o fa ina monamona wo inu ile re
Bi o ba pon dandan fun o lati fi oruko sile ni opolopo awon ibi wonyi ki o to le gbe ninu aye iparun yi, melomelo wa ni ti orun? Se ko ha ye ki a fi oruko re sile si orun nisisiyi, bi o ba je wipe lehin iku, o nilati gbe nibe ninu ayo ati alafia ninu gbogbo ayeraye ti kii dibaje? Beeni, o pon dandan ki a fi oruko re sile nisisiyi.
Kinni o nilati se ki a le fi oruko re sile nibe? Ki a to le fi oruko re sile nibe, a gbodo koko bi o gegebi okan ninu ebi Olorun ni orun. Nipa eyi ni a ka ninu Bibeli Mimo wipe: “ Ṣugbọn iye awọn ti o gbà a, awọn li o fi agbara fun lati di ọmọ Ọlọrun, ani awọn na ti o gbà orukọ rẹ̀ gbọ́” (Johannu 1:12). Bi iwo ba gba Jesu Oluwa gbo pelu gbogbo okan re ti o si gba A gegebi Olugbala ati Oluwa re, iwo yio di omo Re. Oun ni eni na ti o ru gbogbo iya ti o ye ki o je nitori ese re lori agbelebu ni Kalfari ti o si ku fun o. Kii se wipe O ku nikan sugbon O tun ji dide ni ojo keta o si wa laaye titi laelae. Bi iwo ba le jewo awon ese ti o ti da lati igba ewe re ni okookan, Oun yio dari awon ese re ji o yio si gba o gegebi omo re. Yio wa fi ayo ati Alafia kun okan re. Fun awon ti o so di omo Re bi iru eyi nigba aye re ni o so wipe, ”Sugbọn ẹ kuku yọ̀, pe, a kọwe orukọ nyin li ọrun” (Luku 10:20). Oruko awon ti won ti gba idariji ese nipa igbagbo ninu Jesu Oluwa ni a ti fi oruko won sile ni orun. Siwaju sii gegebi bi Bibeli ti wipe, “Ẹnikẹni ti a ti ipa Ọlọrun bí, ki idẹṣẹ; nitoriti irú rẹ̀ ngbe inu rẹ̀: kò si le dẹṣẹ nitoripe a ti ti ipa Ọlọrun bi i” (1 Johannu 3:9), Jesu Oluwa fun iru awon bee ni ore ofe lati gbe igbe aye ti o mo ninu aye ese yi lai dese mo. Siwaju si, nigbati Jesu Oluwa ku lori agbelebu, ko ru ese re nikan bikose aarun re pelu. Nitorina awon ti o gba A gbo le gbe igbe aye ilera nipa gbigba itusile kuro ninu awon aisan koda awon aisan ti ko gboogun.
Bi eyi ba ri bee, kinni yio wa je opin awon ti a ko ko oruko won sile ni orun? Nipa awon ohun ti yio sele si won ni ojo idajo, lehin iku, a ti koo wipe, “Bi a ba si ri ẹnikẹni ti a kò kọ orukọ rẹ̀ sinu iwe ìye, a sọ ọ sinu adagun iná” (Ifihan 20:15).
Eje Jesu fun o ni idariji – nipa mimu ese re kuro. Agbelebu re fun o ni ibukun – nipa mimu egun re kuro. Ina re fun o ni imularada kuro ninu awon aisan re. Iku re fun o ni igboya – nipa mimu iberu re fun iku kuro. Nipa iye Kristi iwo na le gba iye ainipekun. A o ko oruko re, kii se sinu aye yi, bikose sinu iwe iye eyi ti o wa ni orun. Loni yi wa sodo Jesu Oluwa ki o le ni Alafia ati ayo tooto eyi ti aye ko le fi funni, ati pelu, anfani lati lo si orun rere lehin igba ti o ba ku. Gba Jesu Oluwa gbo ki o si gba adura yi:
“Jesu Oluwa, mo gba O gbo mo si fi gbogbo aye mi fun O. We mi mo ki o si so mi di mimo kuro ninu ese mi nipa eje mimo re. Gba mi gegebi omo re ki o ko oruko mi si orun rere nisisiyi. Lati isisiyi lo, titi gbogbo ojo aye mi emi yio gbe igbe aye mi gegebi omo Re. Amin.”
You can find equivalent English tract @