10 / 100

LIVE TO DIE12

Download PDF Tracts

A wa Laaye lati Ku bi? Rara o, A wa laaye titi Lae

Itesiwaju ti de ba imo ijinle ni opolopo ona, koda titi o fi de inu ofurufu, sugbon oro nipa iku ni ko si iwadi ijinle gidi kan nipa re. Iwonba die ninu awon dokita, onimo ijinle ati awon amoye ni o ti se iwadi lori oro Iku tabi ohun ti Iku ja mo ati ohun ti yio sele lehin Iku. Gbogbo igba ni awon onimo ijinle nse atupale awon ohun ti o ruju ni ti otito nipa ago ara eniyan ati akoko kukuru ti o ni lati lo lori ile aye, nipa awon ohun aifojuri ti o kere ju, ati nipa awon ajalu isele abami sugbon die ni eko ti o da lori isele abami ti o je opin iwalaye gbogbo eniyan laye ti a npe ni Iku. Awon eniyan perete ni o jo wipe won tile ni ife si I lati ko eko nipa Iku, sibe o ngbe awon onimo ijinle mi beeni ko yo awon ojogbon sile pelu. Igba gbogbo ni a nni iriri irora, ekun, aisan, ipalara, eru, ibanuje, ikoro okan, ijakule ati aini titi di igba ti Iku funrare yio gbe wa mi, ti a ko si ni le pada si ori ile alaaye mo. Ni kete ti omo eniyan ba ti jade ninu iya re sinu imole oorun, o dabi eni wipe o ti fi owo bo iwe adehun pelu Iku. Ko si wipe boya mo fe tabi nko fe nibe rara. Bibeli wipe, “Nitori gbogbo eniyan ni o sa ti se, ti won si ti kuna ogo Olorun.” “Nitori Iku ni ere ese” (Romu 3:23;6:23). “Niwọn bi a si ti fi lelẹ fun gbogbo enia lati kú lẹ̃kanṣoṣo, ṣugbọn lẹhin eyi idajọ” (Heberu 9:27). Enikookan wa ni yio ku dandan; bi a ba si ti wa ya wa nipa pelu Olorun ninu aye yi, a ko ni le wa pelu re titi ayeraye. A o wa padanu awon ebun iye bii ife, ayo, ewa, otito, alafia, ati idunnu titi lae a o si jiya irora Iku titi ayeraye ninu inira, okunkun, idanikanwa, itiju, ati abamo. Enikansoso nikan na o ti I le tu asiri ijinle nipa Iku ti o si fi han iran eniyan ni ti “Ona Titun ati ti Aaye” si iye ati aiku, Jesu Kristi Olugbala wa, “ẹniti o pa ikú rẹ́, ti o si mu ìye ati aidibajẹ wá si imọlẹ nipasẹ ihinrere” (II Tim. 1:10). Gbogbo itan ni o nii se pelu Re, ibi Re sinu aye ni o pin itan aye si B.C. (ounka odun Saaju Ibi Kristi) ati A.D. (Ounka odun Lehin Ojo Oluwa (Jesu)). Igbe aye ati iku Re ni o dooyika A, bi o ti ku fun ese wa, a sin I, ti a si ji I dide nipa agbara Olorun ni isegun lori ese, iku, orun apaadi ati isa-oku. Ogunlogo awon omo-ehin Re je eleri ojukoju ni ti ajinde Re, egbeegberun eniyan kaakiri agbaye loni na njeri wipe looto ni O wa laaye. “Emi li ẹniti o mbẹ lãye, ti o si ti kú; si kiyesi i, emi si mbẹ lãye si i titi lai, Amin; mo si ní kọkọrọ ikú ati ti ipo-oku” (Ifihan1:18) Jesu re ara Re sile titi de oju iku ori agbelebu. O to iku wo fun gbogbo eniyan “Awa ri ẹniti a dá rẹlẹ̀ diẹ jù awọn angẹli lọ, ani Jesu, ẹniti a fi ogo ati ọlá dé li ade nitori ijiya ikú; ki o le tọ́ iku wò fun olukuluku enia nipa õre-ọfẹ Ọlọrun; ki o le ti ipa ikú pa ẹniti o ni agbara ikú run, eyini ni Eṣu; ki o si le gbà gbogbo awọn ti o ti itori ibẹru iku wà labẹ ìde lọjọ aiye wọn gbogbo” (Heb.2:9,14,15).. Ni akoko Re lori ile aye, Jesu Kristi koni taratara nipa iye, iku, ati aiku. O fi ara han wipe Oun gangan ni Ajinde ati Iye nipa sise iwosan awon ti o nsaisan ti ko gboogun, jiji awon oku si iye, lila oju afoju, mimu ki aditi gboran, ati nipa mimu aro rin. O koni ni igbe aye igbagbo tio ye kooro ninu Olorun O si fi ona iyanu ba aini ti ara awon ti won to O wa fun iranwlowo pade. Pelu ifesemule eko ti o daniloju, O koni nipa iye lehin iku. Tinutinu ni o fi ru ese wa ti o si gba iya wa sori ara Re lori agbelebu. Lehinna Jesu ji dide pelu isegun ki a lee gba A gbo ki a si mo pe Oun ni Ona, Otito, ati Iye. Ona na – Jesu ni Ona Iye Eni na ti o mu o wa si odo Olorun Baba ni siso o di asegun lori idanwo gbogbo, ki iwo na le ko iku loju laisi eru ati ninu idaniloju iye ayeraye. Otito na – Jesu ni Otito na ti okan re ti npomgbe fun lati mo, Eni na ti yio tu o sile kuro lowo ese ati eru. Iye na – Jesu ni Iye Ayeraye eyi ti iku ti ara yi ko le fi opin si, Iye ti a o fi ara aidibaje ati aiku wo ni aso. Laipe, angeli Iku ti o banileru yio wa beere emi re lowo re, yala nipa ijamba, aisan tabi ojo ogbo. Ki o to segbe titi ayeraye sinu Iku ayeraye, kiyesi bi o ti nilo Jesu Kristi to. O wipe, “Emi ni ajinde, ati ìye: ẹniti o ba gbà mi gbọ́, bi o tilẹ kú, yio yè” (Johannu 11:25). Gbagbo ninu Jesu Kristi Oluwa, Ronupiwada ese re, ki o si gba A gegebi Olugbala re. Iku ko ni le lagbara lori re mo gegebi Olorun yio se fi Emi iwa-mimo eyi ti o ji Kristi dide kuro ninu oku kun inu re. Wa, fetisile ki o si keko. Otito yio so o di ominira kuro lowo ese ati Iku. Jesu Kristi, Eni na tii se Ajinde ati Iye npe o lati wa gba eyi. Adura: “Jesu Oluwa mi owon, mo kiyesi wipe mo ni aye kansoso lati gbe, eyi ti yio wa si opin laipe. Mo mo pe elese ni mi. Gbogbo dukia ati gbogbo awon ore ti mo ni ko le gba mi. Mo wa sodo Re pelu okan irele ati iwariri. Mo ronupiwada awon ese mi gbogbo. Jowo dariji mi ki o si we mi mo. Mu mi setan lati pade Re. Amin.”

You can find equivalent English tract @

Live to die no live forever