O JE ENI KAN TI O SE PATAKI
Bi mo se nka iwe irohin atigbadegba kan ni ojo kan bayi, mo se alabapade oro kan ti o gun mi lokan. O ka wipe “Enikookan ni o gbodo je enikan fun enikan, ki o to le je ohun kan.” Mo dake die ki n to tun ka a leekan si “ENIKOOKAN ni o gbodo je ENIKAN fun ENIKAN ki o to le je OHUN KAN.” Iru oro alarojinle wo ni eyi!
Ni aye ero ayara bi asa yi ninu eyi ti a ti nfi awon abajade iwadi ijinle dipo ise eniyan, a ko naani sise pataki eniyan mo. A ko mo iyi ara wa mo yala l’okunrin tabi lobinrin, omonikeji ko ja mo nkankan si wa mo. Otito ni wipe awon die wa ti won di olokiki nigba agbara, ebun orin, ebun ere idaraya ati beebee lo; awon wonyi le di gbajugbaja lawujo, sugbon ogunlogo eniyan ni a nba pade loju popo ti o ngba egbe wa koja lainaani.
Gegebi awari Omowe Donald Forman ti Unifasiti Ise Isegun ti North Western, USA, iye owo gbogbo eroja ago ara eniyan ko ju owo dola meta ati aabo ($3.50) lo. Ni akoko ti iye owo wa sile, gbogbo iye owo eroja ara eniyan ko ju aadorun owo senti Amerika (90cents) lo. Ni ibi ti aye nlo bayi eniyan ko tile ja mo nkankan. Opolopo igba ni agara ma nda tomode tagba ninu ero wipe bi o ti wu ki won se laalaa to, awujo ki i ri won, bee ni won ko la ipa kankan ninu aye. Won kan je alainilaari rara lasan!
Ninu Bibeli, Jesu pa owe aguntan kan ti o sonu. Itan yi ni a ri ninu Ihinrere ti Luku Ori Keedogun. Nibe ni a ri Oluso Aguntan kan ti o ni ogorun aguntan. Sugbon okan ninu won sonu. O fi mokandin logorun sile o si wa okan ti o sonu lo. Opo ewu lo wa l’ona, sugbon o di dandan fun u lati wa aguntan eyi ti o sonu na. Lehin o rehin, o ri I. Beeni, o ri i! O gbe e le ejika re, o gbe e lo sile, o pe awon aladugbo re o si wi fun won pe; “E ba mi yo, mo ti ri aguntan mi ti o sonu.” Eyo aguntan kan soso sugbon o se pataki si oluso aguntan na. “Emi ni oluṣọ-agutan rere: oluṣọ-agutan rere fi ẹmí rẹ̀ lelẹ nitori awọn agutan.(Johannu 10:11).
Iwo na le dabi aguntan ti o sonu yi, ti o ti sako jina sile ati sinu agbo. Sugbon si oluso aguntan rere na. o je eniti o se pataki lopolopo. Si I (Jesu) o niye lori ju apapo gbogbo aye lo, o se pataki ju emi Oun tikarare lo. Bibeli wipe “Nigbati awa jẹ ẹlẹṣẹ, Kristi kú fun wa.(Romu 5:8). O tun soro nipase woli Isaiah: “Obinrin ha lè gbagbe ọmọ ọmú rẹ̀ bi, ti kì yio fi ṣe iyọ́nu si ọmọ inu rẹ̀? Lõtọ, nwọn le gbagbe, ṣugbọn emi kì yio gbagbe rẹ.” (Isaiah 49:15). Oro re ka A lara. Ipokipo ti o wu ki o wa lowolowo, o niye lori lopolopo loju Re. O je ENIKAN PATAKI!
Olukawe, ki o to so iwe ilewo yi nu, kiyesi otito yi. Iwo kii se enikan saa lasan ti awan eniyan ko mo lawujo. O le ro bee – wipe ko si eni ti o nse aajo re, ko si eni ti o ma ngbo o ye. Sugbon Enikan wa ti o nse aajo, ti o le gbo o ye, ife okan wa ni lati mu o mo eni yii, Jesu Kristi Oluwa. O je ENI PATAKI si I, eni ti o ye lati gbala, eni ti o to lati ku fun, eni ti o se’yebiye ti o si niye lori lopolopo loju Re. Jesu feran re. O ku lati gba o la; O wa laaye lati dari ji o, lati fun o ni alafia, ayo ati itelorun ti o nwa kiri. O le sunmo Jesu ki o si di omo Re.
O le so wipe, “ Mo ti rin jina, ko si ireti fun mi mo, awon iwa ibi mi ti mu mi leru ko si si eni na ti o le ranmi lowo.” Oke ainiye eniyan – odomode ati agba – ni won ti ti ipase Jesu ri ireti titun, iye titun, ayo, alafia, eredi ati afojusun fun igbe aye won. Ninu Kristi, won ri igbe aye ti o ye lati gbe. Eyi na le je ipin tire na bi o ba le yonda aye re fun Jesu Kristi. O le sele si iwo na loni- NISISIYI!
ADURA: “Oluwa, elese ni mi. Jowo dariji mi. Emi ko le ran ara mi lowo, nitorina mo wa s’odo Re bi mo ti ri. Mo gbagbo wipe O feran mi nitori eyi ni O fi ku fun mi. Ran mi lowo lati kehin si igbe aye atijo mi ki nsi le tele O ni gbogbo ojo aye mi. Mo gba O gegebi Olugbala ati Olorun mi. Mo fi gbogbo aye mi fun O. Ni Oruko Jesu. Amin.”
You can find equivalent English tract @