hell or heaven_updated

O nilati yan Orun-rere tabi Orun-apaadi

Ewo ni Iwo yio yan? Nibo ni iwo yio ti lo ayeraye re?

Ki o to se ipinnu re, jowo kiyesi awon otito wonyi:

  1. Gbogbo eniyan ni o ni adehun pelu iku ati pelu Olorun.

“Niwọn bi a si ti fi lelẹ fun gbogbo enia lati kú lẹ̃kanṣoṣo, ṣugbọn lẹhin eyi idajọ” Heberu 9:27

  1. Gbogbo eniyan ni a bi ni elese, a bi wa sinu ese, eyi ti a jogun lati odo okunrin akoko, Adamu,eniti o dese si Olorun..

“Kiyesi i, ninu aiṣedede li a gbe bi mi: ati ninu ẹ̀ṣẹ ni iya mi si loyun mi.” Orin Dafidi 51:5. “Nitori gẹgẹ bi ẹ̀ṣẹ ti ti ipa ọdọ enia kan wọ̀ aiye, ati ikú nipa ẹ̀ṣẹ; bẹ̃ni ikú si kọja sori enia gbogbo, lati ọdọ ẹniti gbogbo enia ti dẹṣẹ̀.” Romu 5:12

  1. Nitorina, eniyan di eru fun esu nitori awon ese re.

“Ẹnikẹni ti o ba ndẹṣẹ, on ni ẹrú ẹ̀ṣẹ… Ti eṣu baba nyin li ẹnyin iṣe, ifẹkufẹ baba nyin li ẹ si nfẹ ṣe” Johannu 8:34, 44.

  1. KO SI ENIKENI TI O LE JA AJABO – nipa lilo ise rere, ibura, ileri, tabi nipa lilo ogbon tabi esin ti aye yi ti a gbe kale lati owo eniyan. O je eru, ko si le se irapada ara re.

“Kò si ẹnikan, bi o ti wù ki o ṣe, ti o le rà arakunrin rẹ̀, bẹ̃ni kò le san owo-irapada fun Ọlọrun nitori rẹ̀. Nitori irapada ọkàn wọn iyebiye ni.” Orin Dafidi 49:7, 8.

  1. Idajo Olorun ti o kehin ni yio je IJIYA AYERAYE fun gbogbo elese ninu adagun ina: nitori Olorun je mimo ko si si enikeni tabi ohunkohun ti o se alaimo ti yio le gbe niwaju Re.

“Nitori ikú li ère ẹ̀ṣẹ” Romu6:23.

Bi o tile je pe gbogbo eniyan ni o je elese ati eru esu, Olorun, ninu ife Re ti ko lafiwe ti se ona abayo kan fun gbogbo awon ti o ba yan lati gbagbo ti won si gbekele awon ona wonyi:

  1. Mo wipe o je elese ki o si RONUPIWADA nipa fifi awon ese re sile ki o si jewo won fun Jesu.

“Nitorina ẹ ronupiwada, ki ẹ si tun yipada, ki a le pa ẹ̀ṣẹ nyin rẹ́.” Ise A. Aposteli 3:19.

“Bi awa ba jẹwọ ẹ̀ṣẹ wa, olõtọ ati olododo ni on lati dari ẹṣẹ wa jì wa, ati lati wẹ̀ wa nù kuro ninu aiṣododo gbogbo” 1Johannu 1:9

  1. Gba Ihinrere gbo fun igbala re nipa pipe oruko Jesu Kristi.

“Ṣugbọn Ọlọrun fi ifẹ On papa si wa hàn ni eyi pe, nigbati awa jẹ ẹlẹṣẹ, Kristi kú fun wa.” Romu 5:8

  1. Gba Ir8bomi ti omi, nitori bi o tile je pe a ti dari ese re ji o nigba ti o ti gbagbo, sibesibe ISEDA ESE ti i se “Okunrin Ogbologboo” di dandan ki o ku ki a si sin i ki iwo ki o le gbe IGBE AYE OTUN PATAPATA.

“Njẹ a fi baptismu sinu ikú sin wa pọ̀ pẹlu rẹ̀.” Romu 6:4

  1. Lehin eyi, o le gba iribomi ti Emi Mimo (pelu eri fifi ede titun soro). Bi esu se nro o lagbara lati sin i ninu ese,  bee na ni Olorun na  yio ro o lagbara nipase Emi Mimo lati sin I ninu ododo ati Iwa mimo.

“Ṣugbọn ẹnyin ó gbà agbara, nigbati Ẹmí Mimọ́ ba bà le nyin: ẹ o si ma ṣe ẹlẹri mi…” Ise A. Aposteli 1:8.

 

O ku si owo re

ORUN APAADI:

Mo yan lati tesiwaju lati maa sin esu ninu ese mi

Mo ko ife Olorun ati irapada ti O ti pese sile fun mi

Mo ti pinnu, nitorina, lati gbe gbogbo ayeraye ninu orun apaadi laisi ona abayo

“Ẹ lọ kuro lọdọ mi, ẹnyin ẹni egun, sinu iná ainipẹkun, ti a ti pèse silẹ fun Eṣu ati fun awọn angẹli rẹ̀” Mattiu 25:41

ORUN RERE:

Mo yan lati sa asala kuro lowo esu ati oko eru re, nipa gbigbagbo ninu irapada ti Olorun ti pese sile fun mi eyi ti o wa ninu Jesu Kristi Oluwa nikansoso.

Mo fe lati gboran ki n si sin Olorun mimo ninu ododo

Mo ti pinnu, gegebi ileri Olorun, lati gbe gbogbo ayeraye pelu Olorun ninu ilu mimo Re.

“O ṣeun, iwọ ọmọ-ọdọ rere ati olõtọ… iwọ bọ́ sinu ayọ̀ Oluwa rẹ.” Mattiu 25:23

 

Fun alaye kikun jowo kan si: contact@sweethourfprayer.net

You can find equivalent English tract @

Heaven or hell